Genesis 46:8-27

8 aÈyí ni orúkọ àwọn ọmọ Israẹli (Jakọbu àti Ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Ejibiti:

Reubeni àkọ́bí Jakọbu.
9Àwọn ọmọkùnrin Reubeni:
Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi.
10Àwọn ọmọkùnrin Simeoni:
Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kenaani.
11Àwọn ọmọkùnrin Lefi:
Gerṣoni, Kohati àti Merari.
12Àwọn ọmọkùnrin Juda:
Eri, Onani, Ṣela, Peresi àti Sera (ṣùgbọ́n Ẹri àti Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani).
Àwọn ọmọ Peresi:
Hesroni àti Hamulu.
13Àwọn ọmọkùnrin Isakari!
Tola, Pua, Jaṣibu àti Ṣimroni.
14Àwọn ọmọkùnrin Sebuluni:
Seredi, Eloni àti Jahaleli.
15Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Lea tí ó bí fún Jakọbu ní Padani-Aramu yàtọ̀ fún Dina ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lápapọ̀.

16Àwọn ọmọkùnrin Gadi:
Sefoni, Haggi, Ṣuni, Esboni, Eri, Arodi, àti Areli.
17Àwọn ọmọkùnrin Aṣeri:
Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn ni Sera.
Àwọn ọmọkùnrin Beriah:
Heberi àti Malkieli.
18Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jakọbu bí nípasẹ̀ Silipa, ẹni tí Labani fi fún Lea ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìn-dínlógún (16) lápapọ̀.

19Àwọn ọmọkùnrin Rakeli aya Jakọbu:
Josẹfu àti Benjamini.
20Ní Ejibiti, Asenati ọmọbìnrin Potifẹra, alábojútó àti àlùfáà Oni, bí Manase àti Efraimu fún Josẹfu.
21Àwọn ọmọ Benjamini:
Bela, Bekeri, Aṣbeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Huppimu àti Ardi.
22Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Rakeli bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlá (14) lápapọ̀.

23Àwọn ọmọ Dani:
Huṣimu.
24Àwọn ọmọ Naftali:
Jasieli, Guni, Jeseri, àti Ṣillemu.
25Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Biliha ẹni tí Labani fi fún Rakeli ọmọ rẹ̀ bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀.

26Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jakọbu sí Ejibiti, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láìka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìn-dín-ní-àádọ́rin (66). 27 bPẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Josẹfu ní Ejibiti àwọn ará ilé Jakọbu tí ó lọ sí Ejibiti jẹ́ àádọ́rin (70) lápapọ̀.
Copyright information for YorBMYO